ADUA IRUN ATITORO OORE [TITORO LODO OLOHUN PE KI O DARI ENI LO SIDI OHUN TI O LOORE LAYE ATI LORUN]

1

Jaabir Ibn Abdullah, ‘ki Olohun O yonu si awon mejeeji . so pe: Ojise Olohun “ki ike ati ola Olohun o maa ba a” a maa ko wa ni bi a o ti se maa wa imo nipa oore ti n be ninu gbogbo nnkan, gege bi o ti se maa n ko wa ni ogba-oro “Suura” Al-Qur’aan, a maa so pe: « Ti enikan yin ba se akolekan atise nnkan kan, ki o ki raka meji yato si irun oranyan, leyin naa ki o maa so pe: [ALLAHUMMA INNEE ASTAKHEEHUKA BI ILMIK, WA ASTAQDIRUKA BI QUDRATIK, WA AS'ALUKA MIN FADHLlKA -L-ADZEEM, FA INNAKA TAQDIRU WA LAA AQDIR, WA TA'ALAM WA LAA A’ALAM, WA ANTA ALLAAMU -L- GUYUUB, ALLAHUMMA IN KUNTA TA'ALAMU ANNA HAADZAA -L-AMRA [Yoo SO ohun ti o fe se naa ni ibi yii] KHAIRUN LEE FEE DEENEE WA MA’HAASHEE WA AAQIBATI AMREE, [AAJILIHI WA AAJILIHI] FAQDIRHU LEE WA YASSIRHU LEE THUMMA BAARIK LEE FEEH, WA IN KUNTA TA'ALAMU ANNA HAADZAA –L-AMRA SHARRUN LEE FEE DEENEE WA MA'AASHEE WA AAQIBATI AMREE, [AAJILIHI WA AAJILIHI] FASRIFHU ANNEE WA -S-RIFNEE ANHU WA -Q-DUR LIYA -L-KHMRA HAITHU KAANA THUMMA ARDHINEE BIHI]. « Iwo Olohun, mo n fi imo Re toro oore Re, mo si n fi agbara Re toro agbara -ati ikapa- lodo Re, mo si n tore lodo Re ninu ajulo Re ti o tobi, nitori wi pe Iwo ni O lagbara “lati se ohun-kohun” emi ko ni agbara, Iwe 1’O mo, emi kò mo, Iwo ni Olumo nipa gbogbo ikoko, ti Iwo Olohun ba mo wi pe ohun ti mo fe se yii [ibi ni a so pe yoo ti wi ohun ti o fe se] oore ni yoo je fun mi ni orun mi ati ni igbesi-aye mi ati atunbotan oro mi, ko akoole re fun mi, si se e ni irorun fun mi, wa fi oore si i fun mi; sugbon ti o ba mo wi pe aburu ni nnkan yii yoo je fun mi ni orun mi ati ni igbesi-aye mi ati atunbotan oro mi, ba mi seri re kuro lodo mi, ki O si seri mi kuro lodo re, ki O wa ko akoole eyi ti o dara ju fun mi nibikibi ti o ba wa, ki O si yo mi ninu pelu re >>. “Eni ti o toro oore [ti n be ninu ohun ti o fe se] lodo Eleda, ti o si gba imoran lodo awon ti won je olugbagbo-ododo ninu awon eda Olohun, ti o si fi ara bale lori oro re -ti ko kanju-, ko ni i se abamo tori pe Olohun Oba-mimo so pe: « Maa se ijiroro lori oro naa pelu won, nigba ti o ba wa pinnu [lati gbe igbese kan] ba Olohun duro >>.

Zaker copied