ADUA TI ENIYAN YOO SE NIGBA TI O BA JI

1

[AL-HAMDU LI-L-LAHI L-LADZEE AH'YAANAA BA’ADA MAA AMAATANAA WA ILAIHI-N-NUSHUUR]. “ Ope ni fun Olohun ti O ta wa ji leyin pipa ti O pa wa, odo Re si ni igbende gbogbo eda yoo je” .

2

[AL-HAMDU LI-L-LAHI -L-LADZEE AAFAANEE FEE JASADEE, WA RADDA ALAIYYA RUUHEE. WA ADZINA LEE BI DZIKRIHI]. « Ope ni fun Olohun oba ti O fun mi ni alaafia ni ara mi, ti o si da emi mi pada si mi lara, ti O si yonda fun mi lati se iranti Re >>.

3

[LAA ILAAHA ILLA -L-LAHU WAHDAHU LAA SHAREEKA LAH, LAHU -L- MULKU WA LAHU -L- HAMD, WA HUWA ALAA KULLI SHAIN IN QADEER, SUBHAANA L-LAH, WA –L-HAMDU Li -L-LAH, WA LAA ILAAHA ILLA L-LAH, WA L-LAHU AKBAR. WA LAA HAWLA WA LAA QUWWATA ILLA BI -L-LAHl -L- ALlYYl -L-ADZEEM RABBI -G-FIRLEE]. « Kò si oba kan ti o to lati fi ododo josin fun yato si Olohun nikan soso, ko si orogun fun Un, tiE ni gbogbo akoso ati gbogbo eyin i se, Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan, mimo ni fun Olohun, ope ni fun Olohun, ko si oba kan ti o to lati fi ododo josin fun yato si Olohun, Olohun l‘O tobi ju, ati pe ko si ogbon kan, ko si si agbara kan leyin Olohun Oba-giga, Oba-titobi, Olohun dari jin mi >>.

4

[INNA FEE KHALOI S-SAMAAWAATI WA -L-ARDHI WA KH’TILAAFLI-L-LAILI WA N-NAHAARI LA AAYAATIN LI ULI'L- AL-BAAB‘ ALLADZEENA YADZ’KURUUNA -L-LAHA QIYAAMAN WA QU’UUDAN WA ALAA JUNUUBIHIM WA YATAFAKKARUUNA FEE KHALQI S-SAMAAWAATI WA -L- ARDHI RABBANAA MAA KHALAQ’TA HAADZAA BAATILAN SUBHAANAKA FAQINAA ADZAABA N-NAAR’ RABBANAA INNAKA MAN TUDKHILI N-NAARA FAQAD AKH’ZAIT AHU WA MAA LI D-DZAALIMEENA MIN ANSAAR‘ RABBANAA INNANAA SAMI’INAA MUNAADIYAN YUNAADEE LI-L-IMAANI AN AAMINUU BI RABBIKUM FA AAMANNAA RABBANAA FAGFIR LANAA DZUNUUBANAA WA KAFFIR AN-NAA SAYYIAATINAA WA TAWAFFANAA MA'A L-ABRAAR‘ RABBANAA WA AATINAA MAA WA ADTANAA ALAA RUSULIKA WA LAA TUKH’ZINAA YAUMA L-QIYAAMATI INNAKA LAA TUKH'LIFU –L-MEE'AAD' FASTAJAABA LAHUM RABBUHUM ANNEE LAA UDEE’U AMALA AAMILIN MINKUM MIN DZAKARIN AU UNTHAA BA’ADUKUM MIN BA’AD FA-L- LADZEENA HAAJARUU WA UKH’RIJUU MIN DIYAARIHIM WA UUDZUU FEE SABEELEE WA QAATALUU WA QUTILUU LA UKAFFIRANNA ANHUM SAYYI'AATIHIM WA LA’UDKHILANNAHUM JANNAATIN TAJ’REE MIN TAH’TIHAA -L-AN'HAARU THAWAABAN MIN INNDI -L-LAHI WA –L-LAHU INDAHU HUSNU THAWAAB‘ LAA YAGURRANNAKA TAQALLUBU I-LADZEENA KAFARUU FEE -L-BILAAD MATAAUN QALEELUN THUMMA MA’AWAAHUM JAHANNAMA WA BI'ISA L-MIHAAD‘ LAAKINI L-LADZEENA T-TAQQAW RABBAHUM LAHUM JANNAATUN TAJ’REE MIN TAH’TIHA -L-AN'HAARU KHAALIDEENA FIHAA NUZULAN MIN INDI -L-LAHI WA MAA INDA –L-LAHI KHAIRUN LI-L- ABRAAR‘ WA INNA MIN AH'LI -L-KITAABI LAMAN YU'UMINU BI -L-LAHI WA MAA UNZILA ILAIKUM WA MAA UNZILA ILAIHIM KHASHI’I’EENA LI-L-LAAH LAA YASH’TARUUNA BI AAYAATI -L-LAHI THAMANAN QALEELAN ULAAIKA LAHUM AJ'RUHUM INDA RABBIHIM INNA –L-LAHA SARI’EEU –L-HISAAB‘ YAA AYYUHA —L LADZEENA AAMANUU -S-BIRUU WA SAABIRUU WA RAABITUU WA-T-TAQUU -L-LAHA LA’ALLAKUM TUFLIHUUN‘]. « Dajudaju awon ami n be fun awon onilaakaye ninu iseda awon sanma ati ile, ati titele [ara won] oru ati osan. Awon ti won maa n se iranti Olohun ni iduro ati ni ijoko ati ni ifegbelele won. ti won si maa n ronu nipa iseda awon sanma ati ile, Oluwa wa! Iwo kò seda awon nnkan wonyi lasan, mimo ni fun Q, tori naa so wa nibi iya ina. Oluwa wa! o daju pe enikeni ti O ba mu wona O ti doju ti i, ki yoo si si oluranlowo kan fun awon alabosi. Oluwa wal dajudaju awa gbo ti olupepe kan n pepe Io sibi igbagbo pe: E gba Oluwa yin gbo, tori naa awa gbagbo. Oluwa wa, dari ese wa jin wa, ki O si pa awon aburu wal fun wa. ki O si pa wa pelu awon eni-rere. Oluwa wal fun wa ni ohun ti O se ni adehun fun wa lati enu awon ojise Re, ma si se te wa ni ojo igbende, dajudaju Iwo ki I ye adehun. Oluwa won si je ipe won pe: Emi ki yoo fi ise ti enikan ninu yin se rare rara, yala okunrin tabi obinrin, ninu apa kan yin ni apa keji ti jade, tori naa awon ti won se hijira “isipopada kuro ni ilu ebo lo si ilu Islam , ti won si le won jade kuro ni awon ile won, ti won si fi ara ni won ni oju-ona Mi, ti won si jagun, ti won si pa won, Mo bura pe dajudaju Emi yoo pa awon aburu won re fun won, N o si mu won wo awon ogba-idera ti awon odo n san ni abe won, eleyii je esan lati odo Olohun. Olohun ni O ni Esan ti o dara ju lodo. Ma se je; ki lilo-bibo awon alaigbagbo ninu awon ilu gbogbo o tan o je raya, Igbadun igba dit; Iasan ni eleyii i se, Ieyin naa ina Jahannama ni ibupadasi won, o si buru ni ito. Sugbon awon ti won n paya Oluwa won, awon ogba-idera ti awon odo n san ni abe won n be fun won, inu re ni won yoo maa be laelae, eyi je ibusosi fun won lati odo Olohun. ohun ti n be lodo Olohun ni o loore ju fun awon oluse-rere. Dajudaju o n be ninu awon ti a fun ni tira -Yahudi ati Nasara- awon ti won gba Olohun gbo, ati ohun ti a so kale fun yin, ati ohun ti a so kale fun won, ti won si maa n rera won sile fun Olohun, ti won kj i si ta awon oro Olohun ni owo pooku, esan awon wonyi n be lodo Oluwa won, dajudaju Oba ti O yara ni isiro ni Olohun. Eyin olugbagbo-ododo e se suuru, e si maa fun awon eniyan ni suuru, e si duro sinsin, ki e si paya Olohun, ki e le baa sori-ire».

Zaker copied